Jobu 20

Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn.

Job 20:3 (UKJV) I have heard the check of my reproach, and the spirit of my understanding causes me to answer.

1Ìgbà náà ní Sofari, ará Naama dáhùn, ó sì wí pé,

2“Nítorí náà ní ìrò inú mi dá mi lóhùn, àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.

3Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn.

4“Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ sílé ayé,

5pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.