15Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀.
16Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.
17Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.
18“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.
19Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.