Jobu 24

“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.

Job 24:18 (UKJV) He is swift as the waters; their portion is cursed in the earth: he beholds not the way of the vineyards.

16Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀.

17Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn.

18“Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà.

19Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀.

20Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀; a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́; bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.