18A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ.
19Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.
20Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé?
21A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.
22Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.