2Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.
3Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí ìṣúra láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.
4Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.
5Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná;
6òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta safire, o sì ní erùpẹ̀ wúrà.