8Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
9“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.
10Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.
11Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.
12Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.