22Ìwọ gbé mi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ mú mi fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátápátá.
23Èmi sá à mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.
24“Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
25Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
26Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé; nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.