24“Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha nawọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubú rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
25Èmi kò ha sọkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún tálákà bí?
26Nígbà tí mo fojú ṣọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé; nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.
27Ikùn mí n ru kò sì sinmi, ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bá mi.
28Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú oòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́.