28èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò, nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
29“Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi. Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a.
30Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀ nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀.
31Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé, ‘Ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?’
32Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí; èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.