2Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá? Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá.
3Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
4Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi?
5“Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn,
6(jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)