15“Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́, wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.
16Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.
17Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.
18Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.
19Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.