13Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe wí pé, ‘Àwa wá ọgbọ́n ní àwárí; Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú kì í ṣe ènìyàn.’
14Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.
15“Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́, wọ́n ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ í sọ.
16Mo sì retí, nítorí wọn kò sì fọhùn, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.
17Bẹ́ẹ̀ ni èmí ó sì dáhùn nípa ti èmi, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.