Jobu 32

Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí, èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

Job 32:20 (UKJV) I will speak, that I may be refreshed: I will open my lips and answer.

18Nítorí pé èmi kún fún ọ̀rọ̀ sísọ, ẹ̀mí ń rọ̀ mi ni inú mi.

19Kíyèsi i, ikùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-awọ tuntun.

20Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí, èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

21Lóòtítọ́ èmi kì yóò ṣe ojúsàájú sí ẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.

22Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.