7Èmi wí pé ọjọ́ orí ni ìbá sọ̀rọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.
8Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.
9Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.
10“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.
11Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín; èmi fetísí àròyé yín, nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;