Jobu 32

“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.

Job 32:10 (UKJV) Therefore I said, Hearken to me; I also will show mine opinion.

8Ṣùgbọ́n ẹ̀mí kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.

9Ènìyàn ńlá ńlá kì í ṣe ọlọ́gbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.

10“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé, ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.

11Kíyèsi i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín; èmi fetísí àròyé yín, nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀yin yóò sọ;

12àní, mo fiyèsí yín tinútinú. Sì kíyèsi i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jobu ní irọ́; tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.