Jobu 35

Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.

Job 35:5 (UKJV) Look unto the heavens, and see; and behold the clouds which are higher than you.

3Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

4“Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.

5Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.

6Bí ìwọ bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbí bí ìrékọjá rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?

7Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fi fún un, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.