19Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí? Tàbí ipa agbára rẹ?
20Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.
21Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú, nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.
22“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni gbéga nípa agbára rẹ̀; ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí rẹ̀?
23Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un, tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?