17Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.
18Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bá a tàn ọ; láti jẹ́ kí títóbi rẹ mú ọ ṣìnà.
19Ọrọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí? Tàbí ipa agbára rẹ?
20Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò ní ipò wọn.
21Máa ṣọ́ra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búburú, nítorí èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.