2“Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fihàn ọ́, nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.
3Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jíjìn wá, èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.
4Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.
5“Kíyèsi i, Ọlọ́run ni alágbára, òun kò i sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.
6Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí, ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.