8Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń ṣe ìtulẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.
9Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé, nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.
10Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnnìún àti eyín àwọn ẹgbọrọ kìnnìún ní a ká.
11Kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ, àwọn ẹgbọrọ kìnnìún sísanra ni a túká kiri.
12“Ǹjẹ́ nísinsin yìí a fi ohun àṣírí kan hàn fún mi, etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.