Jobu 5

Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.

Job 5:10 (UKJV) Who gives rain upon the earth, and sends waters upon the fields:

8“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe tèmi, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní èmi yóò ti ṣìpẹ̀, ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi yóò máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.

9Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí, ohun ìyanu láìní iye.

10Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé tí ó sì ń rán omi sínú ilẹ̀kílẹ̀.

11Láti gbé àwọn orílẹ̀-èdè lékè kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.

12Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.