Jobu 5

Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán; wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.

Job 5:14 (UKJV) They meet with darkness in the day time, and grope in the noonday as in the night.

12Ó yí ìmọ̀ àwọn alárékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdáwọ́lé wọn ṣẹ.

13Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àrékérekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tì ṣubú ní ògèdèǹgbé.

14Wọ́n sáré wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán; wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru ni.

15Ṣùgbọ́n ó gba tálákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún tálákà, àìṣòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.