Jobu 5

Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.

Job 5:3 (UKJV) I have seen the foolish taking root: but suddenly I cursed his habitation.

1“Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn? Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí?

2Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye, ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.

3Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.

4Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.

5Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa sọ̀ di jíjẹ, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀gún lọ kó, àwọn ìgárá ọlọ́ṣà sì gbé ohun ìní wọn mì.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.