1“Ó jẹ́ pé nísinsin yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn? Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó yípadà sí?
2Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye, ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.
3Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójúkan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.