14“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá, kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?
15Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.
16Tí ó dúdú nítorí omi dídì, àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.
17Nígbàkígbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ, nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.
18Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn, wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.