27Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba, ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.
28“Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín. Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé, ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.
29Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀; àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.
30Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi? Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?