25Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?
26Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.
27Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba, ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.
28“Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín. Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé, ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.
29Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀; àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.