9Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Beari àti Orioni, Pleiadesi àti ìràwọ̀ púpọ̀ ti gúúsù.
10Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwárí lọ, àní ohun ìyanu láìní iye.
11Kíyèsi i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwájú, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
12Kíyèsi i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà? Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?
13Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn, àwọn onírànlọ́wọ́ ti Rahabu a sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.