21“Olóòótọ́ ni mo ṣe, síbẹ̀ èmi kò kíyèsi ara mi, ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.
22Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi ṣe sọ: ‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’
23Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì, yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.
24Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú; ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
25“Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.