23Bí ìjàǹbá bá pa ni lójijì, yóò rẹ́rìn-ín nínú ìdààmú aláìṣẹ̀.
24Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú; ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
25“Ǹjẹ́ nísinsin yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
26Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eèsún papirusi tí ń sáré lọ; bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
27Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi, èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’