1Jobu sì dáhùn ó sì wí pé,
2“Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́. Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
3Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà, òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọ̀rọ̀.
4Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun. Ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
5Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́: tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.