3Bí ó bá ṣe pé yóò bá a jà, òun kì yóò lè dalóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rún (1,000) ọ̀rọ̀.
4Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òun. Ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
5Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́: tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀.
6Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì.
7Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn, kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.