17Nítorí náà, wọ́n sì tún wí fún afọ́jú náà pé, “Kí ni ìwọ ní wí nípa rẹ̀, nítorí tí ó là ọ́ lójú?” Ó sì wí pé, “Wòlíì ní í ṣe.”
18Nítorí náà àwọn Júù kò gbàgbọ́ nípa rẹ̀ pé ojú rẹ̀ ti fọ́ rí, àti pé ó sì tún ríran, títí wọ́n fi pe àwọn òbí ẹni tí a ti là lójú.
19Wọ́n sì bi wọ́n léèrè wí pé, “Ǹjẹ́ èyí ni ọmọ yín, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, a bí ní afọ́jú? Báwo ni ó ṣe ríran nísinsin yìí?”
20Àwọn òbí rẹ̀ dá wọn lóhùn wí pé, “Àwa mọ̀ pé ọmọ wa ni èyí, àti pé a bí i ní afọ́jú,
21ṣùgbọ́n bí ó tí ṣe ń ríran nísinsin yìí àwa kò mọ̀, ẹni tí ó là á lójú, àwa kò mọ̀, ẹni tí ó ti dàgbà ni òun; ẹ bi í léèrè, yóò wí fúnra rẹ̀.”