17Mo ti jìnnà sí àlàáfíà; mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
18Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ àti ìrètí mi nínú Olúwa.”
19Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi, ìkorò àti ìbànújẹ́.
20Mo ṣèrántí wọn, ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.