27Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.
28Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.
29Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.
30Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
31Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.