Mika 1

Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa. Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli yóò sì wá sí Adullamu.

Micah 1:15 (UKJV) Yet will I bring an heir unto you, O inhabitant of Mareshah: he shall come unto Adullam the glory of Israel.

13Ìwọ olùgbé Lakiṣi, dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára. Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin Sioni, nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.

14Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún Moreṣeti Gati. Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli.

15Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa. Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli yóò sì wá sí Adullamu.

16Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára, sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún, nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.