7Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa, bí ọ̀wààrà òjò lórí koríko, tí kò gbẹ́kẹ̀lé ènìyàn tàbí kò dúró de àwọn ọmọ ènìyàn.
8Ìyókù Jakọbu yóò sì wà láàrín àwọn aláìkọlà ní àárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn, bí i kìnnìún láàrín àwọn ẹranko inú igbó, bí i ọmọ kìnnìún láàrín agbo àgùntàn, èyí tí ó máa ń fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, tí ó sì máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, tí kò sì ṣí ẹnìkan tí ó lè gbà á là.
9A ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sì ni a ó parun.
10“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.
11Èmi yóò sì pa ilẹ̀ ìlú ńlá rẹ̀ run, èmi ó sì fa gbogbo ibi gíga rẹ̀ ya.