Nehemiah 11

Nísinsin yìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jerusalẹmu, àwọn ènìyàn tókù sì dìbò láti mú ẹnìkọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tókù yóò dúró sí àwọn ìlú u wọn.

Nehemiah 11:1 (UKJV) And the rulers of the people dwelt at Jerusalem: the rest of the people also cast lots, to bring one of ten to dwell in Jerusalem the holy city, and nine parts to dwell in other cities.

1Nísinsin yìí àwọn olórí àwọn ènìyàn tẹ̀dó sí Jerusalẹmu, àwọn ènìyàn tókù sì dìbò láti mú ẹnìkọ̀ọ̀kan jáde nínú àwọn mẹ́wàá mẹ́wàá láti máa gbé ní Jerusalẹmu, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án tókù yóò dúró sí àwọn ìlú u wọn.

2Àwọn ènìyàn súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn láti gbé ní Jerusalẹmu.

3Wọ̀nyí ni àwọn olórí agbègbè ìjọba tí wọ́n tẹ̀dó sí Jerusalẹmu (díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ìran àwọn ìránṣẹ́ Solomoni ń gbé àwọn ìlú Juda, olúkúlùkù ń gbé lórí ilẹ̀ ìní rẹ̀ ní àwọn ìlú náà.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.