Nehemiah 11

Àwọn ìran Peresi tó gbé ní Jerusalẹmu jẹ́ àádọ́rinlénírinwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.

Nehemiah 11:6 (UKJV) All the sons of Perez that dwelt at Jerusalem were four hundred threescore and eight valiant men.

4Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu). Nínú àwọn ọmọ Juda: Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi;

5àti Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Koli-Hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣilo.

6Àwọn ìran Peresi tó gbé ní Jerusalẹmu jẹ́ àádọ́rinlénírinwó ó dín méjì (468) alágbára ọkùnrin.

7Nínú àwọn ìran Benjamini: Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Joẹdi, ọmọ Pedaiah, ọmọ Kolaiah, ọmọ Maaseiah, ọmọ Itieli, ọmọ Jeṣaiah,

8àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Gabbai àti Sallai jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rún ó lé mẹ́jọ (928) ọkùnrin.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.