21Nígbà náà ní ó rí ará Keni ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Ibùgbé rẹ ní ààbò, ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta;
22síbẹ̀ ẹ̀yin ará Keni ni yóò di píparun nígbà tí Asiria bá mú yín ní ìgbèkùn.”
23Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?
24Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdókọ̀ Kittimu; wọn yóò ṣẹ́gun Asiria àti Eberi, ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.”
25Nígbà náà ni Balaamu dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Balaki sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.