Obadiah 1

Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀ nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó, ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

Obadiah 1:13 (UKJV) You should not have entered into the gate of my people in the day of their calamity; yea, you should not have looked on their affliction in the day of their calamity, nor have laid hands on their substance in the day of their calamity;

11Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ, tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

12Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ, ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda, ní ọjọ́ ìparun wọn ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.

13Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀ nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó, ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.

14Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò. Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.

15“Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn kèfèrí. Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà; ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.