Òwe 12

Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.

Proverbs 12:2 (UKJV) A good man obtains favour of the LORD: but a man of wicked devices will he condemn.

1Ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ ẹ̀kọ́ fẹ́ ìmọ̀, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìbáwí jẹ́ aláìgbọ́n.

2Ènìyàn rere gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n ènìyàn ètè búburú ni yóò dá lẹ́bi.

3A kò lè fi ẹsẹ̀ ènìyàn múlẹ̀ nípa ìwà búburú ṣùgbọ́n a kò le è fa olódodo tu.

4Aya oníwà rere ni adé ọkọ rẹ̀ ṣùgbọ́n aya adójútini dàbí inú egungun rẹ̀ jẹrà.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.