32Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀, kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
33Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.
34Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè, ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.
35Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́n ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.