30Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara, ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà.
31Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hàn ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run.
32Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀, kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò.
33Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóye kódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun.
34Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè, ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.