Òwe 16

Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

Proverbs 16:15 (UKJV) In the light of the king's countenance is life; and his favour is as a cloud of the latter rain.

13Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́, wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.

14Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́ ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

15Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè; ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

16Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ àti láti yan òye dípò o fàdákà!

17Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi, ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.