11Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára; yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.
12Fi àyà sí ẹ̀kọ́, àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀.
13Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú.
14Bí ìwọ fi pàṣán nà án, ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì.
15Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n, ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú.