Òwe 26

Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.

Proverbs 26:26 (UKJV) Whose hatred is covered by deceit, his wickedness shall be showed before the whole congregation.

24Ènìyàn tí ó kórìíra máa ń fi ètè rẹ̀ bo àṣírí ara rẹ̀ ṣùgbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ ni ìtànjẹ wà.

25Bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tilẹ̀ fanimọ́ra, má ṣe gbà á gbọ́ nítorí ìríra méje ni ó kún inú ọkàn rẹ̀.

26Ìkórìíra rẹ le è fi ara sin nípa ẹ̀tàn ṣùgbọ́n àṣírí ìwà búburú rẹ̀ yóò tú ní gbangba.

27Bí ènìyàn kan bá gbẹ́ kòtò, yóò ṣubú sínú rẹ̀. Bí ẹnìkan bá ju òkúta, yóò padà sọ́dọ̀ òun tìkára rẹ̀.

28Ahọ́n ẹ̀tàn máa ń kórìíra àwọn tí ó ṣe ní ìkà, ẹnu ìtànjẹ sì máa ń pa ni run.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.