Òwe 28

Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀, ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́.

Proverbs 28:2 (UKJV) For the transgression of a land many are the princes thereof: but by a man of understanding and knowledge the state thereof shall be prolonged.

1Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.

2Nígbà tí orílẹ̀-èdè bá ní orí kunkun, àwọn ọba rẹ̀ a máa pọ̀, ṣùgbọ́n olóye àti onímọ̀ a máa pa òfin mọ́.

3Ọba tí ó ni àwọn tálákà lára dàbí àgbàrá òjò tí ó ń gbá gbogbo ọ̀gbìn lọ.

4Àwọn tí ó kọ òfin sílẹ̀ a máa gbóríyìn fún ènìyàn búburú ṣùgbọ́n àwọn tí ó pa òfin mọ́ kọjú ìjà sí ènìyàn búburú.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.