Òwe 7

Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.

Proverbs 7:7 (UKJV) And beheld among the simple ones, I discerned among the youths, a young man void of understanding,

5Wọn yóò pa ó mọ́ kúrò lọ́wọ́ obìnrin alágbèrè, kúrò lọ́wọ́ àjèjì obìnrin àti ọ̀rọ̀ ìtànjẹ rẹ̀.

6Ní ojú fèrèsé ilé è mi mo wo ìta láti ojú fèrèsé.

7Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.

8Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀.

9Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. Licensed CC BY-SA 4.0. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc.