7Mo rí i láàrín àwọn aláìmọ̀kan mo sì kíyèsi láàrín àwọn ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́ kan tí ó ṣe aláìgbọ́n.
8Ó ń lọ ní pópónà ní tòsí i ilé alágbèrè obìnrin náà, ó ń rìn lọ sí ọ̀nà ilé e rẹ̀.
9Ní ìrọ̀lẹ́ bí oòrùn ṣe ń wọ̀, bí òkùnkùn ṣe ń bo ni lára.
10Bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan jáde wá láti pàdé rẹ̀, ó múra bí panṣágà pẹ̀lú ètè búburú.
11(Ó jẹ́ aláriwo àti alágídí, ìdí rẹ̀ kì í jókòó nílé;